Ninu Gbogbo Ewu Oru

Ninu Gbogbo Ewu Oru
“Emi dubule, mo si sun; mo si ji; nitoriti Oluwa ti mi lehin.” -Orin 3:5

 1. Ninu gbogbo ewu oru
  Oluwa l’o nso wa;
  Awa tun ri imole yi,
  A tun te ekun ba.
 2.  

 3. Oluwa, pa wa mo loni
  Fi apa Re so wa;
  Kiki awon t’Iwo pamo’
  L’o nyo ninu ewu.
 4.  

 5. K’oro wa ati iwa wa
  Wipe Tire l’awa;
  Tobe t’imole otito
  Le tan l’oju aiye;
 6.  

 7. Ma je k’a pada lodo Re,
  Olugbala owon;
  Titi ao fi oju wa ri
  Oju re nikehin. Amin.


Onkowe: Thomas Kelly

»English – Through All The Dangers Of The Night


Listen Now

1 comment

Download Gospel Live App